Jeremáyà 47:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nítorí tí ọjọ́ náà ti péláti pa àwọn Fílístínì run,kí a sì mú àwọn tí ó làtí ó lè ran Tírè àti Sídónì lọ́wọ́ kúrò. Olúwa ti ṣetán láti pa Fílístínì run,àwọn tí ó kù ní agbègbè Káfútò.

5. Gásà yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.A ó pa Áṣíkélónì lẹ́nu mọ́;ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,ìwọ yóò ti ṣá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

6. “Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?Padà sínú àkọ̀ re;sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’

Jeremáyà 47