Jeremáyà 46:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa:Àwọn orílẹ̀ èdè:

2. Nípa Éjíbítì,Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò Ọba Éjíbítì ẹni tí a borí rẹ̀ ní Káṣímísì, ní odò Ẹ́fúrétà láti ọwọ́ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ní ọdún kẹrin Jéhóáíkímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà:

3. “Pèsè ọ̀kọ̀ rẹ sílẹ̀, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí o sì yan lọ síta fún ogun!

4. Di ẹṣin ní gàárì,kí ẹ sì gùn ún.Ẹ dúró lẹ́sẹsẹpẹ́lú àsíborí yín!Ẹ dán ọ̀kọ̀ wò,kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

5. Kí ni nǹkan tí mo tún rí?Wọ́n bẹ̀rù,wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.Wọ́n sá,wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”ni Olúwa wí.

Jeremáyà 46