24. Nígbà náà ni Jeremáyà dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Júdà tí ó wà ní Éjíbítì.
25. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ lórí sísun tùràrí àti dída ọtí sí orí ère ayaba ọ̀run ṣẹ.’“Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.
26. Ṣùgbọ́n gbọ ọ̀rọ̀ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì, mo gégùn-ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ‘wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Júdà tí ń gbé ibikíbi ní Éjíbítì ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra. “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láàyè.”
27. Nítorí náà, mò ń wò wọ́n bí i fún ìparun, kì í ṣe fún rere. Àwọn Júù tí ó wà ní Éjíbítì yóò parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi parun.