Jeremáyà 38:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá Ọba sọ tàbí ohun tí Ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’

26. nígbà náà kí o sọ fún wọn, ‘Mò ń bẹ Ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jónátanì láti lọ kú síbẹ̀.’ ”

27. Gbogbo àwọn olóyè sì wá sí ọ̀dọ̀ Jeremáyà láti bi í léèrè, ó sì sọ gbogbo ohun tí Ọba ní kí ó sọ. Wọn kò sì sọ ohunkóhun mọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun àti Ọba jọ sọ.

28. Jeremáyà wà nínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kó Jérúsálẹ́mù

Jeremáyà 38