Ó lè jẹ́ wí pé ilé Júdà yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn; kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀. Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n.”