32. Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn ènìyàn Júdà ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ ni wọn tí wọ́n ṣe. Àwọn Ísírẹ́lì, Ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù.
33. Wọ́n kọ ẹ̀yìn sími, wọ́n sì yí ojú wọn padà. Èmi kọ̀ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbiara sí ìwà ìbàjẹ́.
34. Wọ́n kó òrìṣà ìríra wọn jọ sí inú ilé tí wọ́n fi orúkọ mi pè, wọ́n sì sọ́ di àìmọ́.
35. Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Báálì ní àfonífojì Hínómù láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rúbọ sí Mólékì. Èmi kò páláṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Júdà ṣe.
36. “Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni à ó fi wọ́n fún Ọba Bábílónì,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nì yìí: