Jeremáyà 31:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Ísírẹ́lì, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.

2. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idàyóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì.”

3. Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,

4. Èmi yóò tún gbé e yín sókè,àní a ó tún gbé e yín ró iwọ wúndíá ilẹ̀ Ísírẹ́lì.Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.

5. Ẹ ó tún dá okoní orí òkè Saáríà;àwọn àgbẹ̀ yóò sì máagbádùn èso oko wọn.

Jeremáyà 31