Jeremáyà 3:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.

16. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa’ kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́.

17. Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jérúsálẹ́mù ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀ èdè yóò péjọ sí Jérúsálẹ́mù láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle burúkú wọn mọ́.

18. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Júdà yóò darapọ̀ mọ́ ilé Ísírẹ́lì. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.

19. “Èmi fúnra mi sọ wí pé,“ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrinkí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.

20. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi.Ìwọ ilé Ísírẹ́lì”ni Olúwa wí.

21. A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga,ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po,wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.

Jeremáyà 3