1. Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jérúsálẹ́mù sí àwọn tí ó yè nínú àwọn aṣàtìpó àti àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn Nebukadinésárì tí wọ́n ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì.
2. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀yìn ìṣèjọba Jéhóíákímù àti ayaba àti ìwẹ̀fà pẹ̀lú àwọn olórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, àwọn gbẹ́nà gbẹ́nà àti àwọn olùyàwòrán tí wọ́n lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù.
3. Ó fi lẹ́tà náà rán Élásà ọmọ Híkáyà ti Ṣédà.
4. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì:
5. “Ó kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.
6. Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fọ́kọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ síi ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá.