9. Ṣùgbọ́n, àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà ni a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì olótítọ́ tí Olúwa rán, tí àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ bá wá sí ìmúṣẹ.”
10. Wòlíì Hananáyà gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremáyà kúrò, ó sì fọ́ ọ.
11. Ó sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni mà á fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì láàrin ọdún méjì.’ ” Jeremáyà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.
12. Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananáyà ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremáyà wí pé: