3. Kí o rán ọ̀rọ̀ sí Ọba ti Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà.
4. Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ:
5. Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi.
6. Nísinsìn yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ fún Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.
7. Gbogbo orílẹ̀ èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè àti àwọn Ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.
8. “ ‘ “Àmọ́ tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀; Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.