10. Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí níyà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún Ọba Bábílónì, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’
11. “Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé Ọba Júdà pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
12. Ilé Dáfídì èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ:“ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀;yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í láraẹni tí a ti jà lólèbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná.Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jóláìsí ẹni tí yóò pa á.
13. Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jérúsálẹ́mùìwọ tí o gbé lórí àfonífojìlórí olókúta tí ó tẹ́jú,Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojú kọ wá?”
14. Èmi yóò jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ni Olúwa wí.Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀;ìyẹn yóò jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”