Jeremáyà 20:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ìgbà tí àlùfáà Pásúrì ọmọkùnrin Ímímérì olórí àwọn ìjòyè Tẹ́ḿpìlì Olúwa gbọ́ tí Jeremáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí.

2. Ó mú kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu ọ̀nà ti Bẹ́ńjámínì ní Tẹ́ḿpìlì Olúwa.

3. Ní ọjọ́ kejì tí Páṣúrì tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremáyà sì sọ fún un wí pé, “orúkọ Olúwa kì í ṣe Páṣúrì fún ọ bí kò ṣe ohun ẹ̀rù.

Jeremáyà 20