Jeremáyà 18:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wá wí pe:

2. “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.”

3. Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.

4. Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.

5. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

6. “Ẹyin ilé Ísírẹ́lì, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.

7. Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun.

8. Tí orílẹ̀ èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà níbi àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.

9. Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀ èdè kan tàbí ìjọba kan.

Jeremáyà 18