10. “Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘È é ṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kínni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’
11. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́.
12. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Ní bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ṣe ń tẹ̀lé ọkàn líle rẹ̀, dípò èyí tí ó yẹ kí ẹ fi gbọ́ tèmi.
13. Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí bàbá yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn Ọlọ́run kékèké ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín.’
14. “Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láàyè Olúwa ń bẹ Ẹni tí ó mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì.’