Jeremáyà 15:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padàwá kí o lè máa sìn mí. Tí ó básọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di ọ̀gbẹnusọmi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn

20. Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbárasí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jàṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹnítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,kí n sì dáàbò bò ọ́,”ni Olúwa wí.

21. “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọnìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”

Jeremáyà 15