Jeremáyà 1:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Mo sọ pé Háà! Olúwa tí ó pọ̀ ní ipá, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.

7. Olúwa sọ fún mi pé, má ṣe sọ pé ọmọdé lásán ni mí. O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.

8. Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.

9. Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsìnyìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ

10. Wòó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀ èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti má a kọ́, àti láti máa gbìn.

11. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé“Kí ni o rí Jeremáyà?” Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi álímọ́ńdi”

12. Olúwa sì wí fún mi pé, “ó ti rí i bí ó se yẹ, torí pé mo ti ń sọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúsẹ.”

13. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ́kèjì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

Jeremáyà 1