15. Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.Àwọn Ọba wọn yóò wágbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú-ọ̀nà à bá wọléJérúsálẹ́mù. Wọn ó sì dìde sí gbogboàyíká wọn àti sí gbogbo àwọnìlú Júdà.
16. Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lóríàwọn ènìyàn mi nítorí ìwàbúburú wọn nípa kíkọ̀ mísílẹ̀, nípa rírúbọ sí Ọlọ́runmìíràn àti sínsin àwọn ohuntí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.
17. “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pa lásẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọn dẹ́rù bà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn.
18. Ní òní èmi ti sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè alágbára, òpó ìrin àti odi idẹ sí àwọn Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
19. Wọn yóò dojú ìjà kọọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.