Jẹ́nẹ́sísì 6:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo.

6. Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.

7. Nítorí náà, Olúwa wí pé “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.”

8. Ṣùgbọ́n, Nóà rí ojúrere Olúwa.

9. Wọ̀nyí ni ìtàn Nóà.Nóà nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ àti aláìlábùkù ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì bá Ọlọ́run rìn.

10. Nóà sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣémù, Ámù àti Jáfétì.

11. Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú.

Jẹ́nẹ́sísì 6