Jẹ́nẹ́sísì 49:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “Ísákárì jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbáratí ó sùn sílẹ̀ láàrin àpò ẹrù méjì.

15. Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó,àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó,yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà,yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá.

16. “Dánì yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

17. Dánì yóò jẹ́ ejo ni pópónààti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,tí ó bu ẹsin jẹ ní ẹṣẹ̀,kí ẹni tí n gùn-un bá à le è subú sẹ́yìn.

18. “Mo ń dúró de ìtúsilẹ̀ rẹ, Olúwa

Jẹ́nẹ́sísì 49