Jẹ́nẹ́sísì 46:32-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.”

33. Nígbà tí Fáráò bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe,

34. ẹ fún-un lésì pé, “àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn ni láti ìgbà ewe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.” Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láàyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì. Nítorí pé àwọn ará Éjíbítì kóríra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.

Jẹ́nẹ́sísì 46