Jẹ́nẹ́sísì 38:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkókò náà, Júdà lọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti lọ dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin ará Ádúlámù kan tí ń jẹ́ Hírà.

2. Júdà sì pàdé ọmọbìnrin Kénánì kan níbẹ ẹni ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Súà. Ó sì fi ṣe aya, ó sì bá a lò pọ̀;

3. ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Érì.

Jẹ́nẹ́sísì 38