Jẹ́nẹ́sísì 36:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Kórà, Gátamù àti Ámálékì. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Élífásì ní Édómù wá, wọ́n jẹ́ ọmọ-ọmọ Ádà.

17. Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Rúélì,Náhátì, Ṣérátì, Ṣámò àti Mísà. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Rúélì jáde ní Édómù. Ọmọ-ọmọ Básémátì aya Ísọ̀ ni wọ́n jẹ́.

18. Àwọn ọmọ Óhólíbámà aya Ísọ̀:Jéúsì, Jálámì, àti Kórà, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olorí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Óhólíbámà ọmọ Ánà, ìyàwó Ísọ̀ wá.

19. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ísọ̀ (Édómù). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn.

20. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣéírì ara Hórì tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà:Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Ánà

Jẹ́nẹ́sísì 36