Jẹ́nẹ́sísì 36:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Wọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Ísọ̀:Àwọn ọmọ Élífásì, àkọ́bí Ísọ̀:Témánì, Ómárì, Ṣéfò, Kénásíà,

16. Kórà, Gátamù àti Ámálékì. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Élífásì ní Édómù wá, wọ́n jẹ́ ọmọ-ọmọ Ádà.

17. Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Rúélì,Náhátì, Ṣérátì, Ṣámò àti Mísà. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Rúélì jáde ní Édómù. Ọmọ-ọmọ Básémátì aya Ísọ̀ ni wọ́n jẹ́.

18. Àwọn ọmọ Óhólíbámà aya Ísọ̀:Jéúsì, Jálámì, àti Kórà, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olorí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Óhólíbámà ọmọ Ánà, ìyàwó Ísọ̀ wá.

19. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ísọ̀ (Édómù). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn.

20. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣéírì ara Hórì tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà:Lótanì, Ṣóbálì, Ṣíbéónì, Ánà

21. Dísónì, Éṣérì, àti Díṣánì, àwọn wọ̀nyìí ọmọ Ṣéírì ni Édómù.

22. Àwọn ọmọ Lótanì:Órì àti Ómámù: Arábìnrin Lótanì sì ni Tímínà.

23. Àwọn ọmọ Ṣóbálì:Álífánì, Mánáhátì, Ébálì, Ṣéfò àti Onámù.

24. Àwọn ọmọ Ṣíbéónì:Áíyà àti Ánà. Èyí ni Ánà tí ó rí ìṣun omi gbígbóná ní inú asálẹ̀ bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣébéónì baba rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 36