Jẹ́nẹ́sísì 33:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jákọ́bù sì gbójú sókè, ó sì rí Ísọ̀ àti irinwó ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Líà, Rákélì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì.

2. Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn ṣíwájú, Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rákélì àti Jóṣẹ́fù sì wà lẹ́yìn pátapáta.

3. Jákọ́bù fúnra rẹ̀ wa lọ ṣíwájú pátapáta, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń sún mọ́ Ísọ̀, arákùnrin rẹ̀.

4. Ṣùgbọ́n Ísọ̀ sáré pàdé Jákọ́bù, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sunkún.

5. Nígbà tí Ísọ̀ sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jákọ́bù, ó bèèrè lọ́wọ́ Jákọ́bù pé, “Ti tani àwọn wọ̀nyí?”Jákọ́bù sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”

6. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba.

7. Lẹ́yìn náà ni Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Jósẹ́fù àti Rákélì dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú.

8. Ísọ̀ sì béèrè pé, “Kín ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ̀ tí mo pàdé wọ̀nyí?”Jákọ́bù dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.”

9. Ṣùgbọ́n Ísọ̀ wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.”

Jẹ́nẹ́sísì 33