1. Jákọ́bù sì gbójú sókè, ó sì rí Ísọ̀ àti irinwó ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Líà, Rákélì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì.
2. Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn ṣíwájú, Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rákélì àti Jóṣẹ́fù sì wà lẹ́yìn pátapáta.
3. Jákọ́bù fúnra rẹ̀ wa lọ ṣíwájú pátapáta, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń sún mọ́ Ísọ̀, arákùnrin rẹ̀.
4. Ṣùgbọ́n Ísọ̀ sáré pàdé Jákọ́bù, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sunkún.
5. Nígbà tí Ísọ̀ sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jákọ́bù, ó bèèrè lọ́wọ́ Jákọ́bù pé, “Ti tani àwọn wọ̀nyí?”Jákọ́bù sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.”