Jẹ́nẹ́sísì 31:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ní ọjọ́ kẹ́ta ni Lábánì gbọ́ pé Jákọ́bù ti sa lọ.

23. Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jákọ́bù, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gílíádì.

24. Ọlọ́run sì yọ sí Lábánì ará Arámáínì lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jákọ́bù, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”

Jẹ́nẹ́sísì 31