Jẹ́nẹ́sísì 31:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jákọ́bù sì gbọ́ pé àwọn ọmọ Lábánì ń wí pé, “Jákọ́bù ti gba gbogbo ohun ìní baba wa, ó sì ti kó ọrọ̀ jọ fún ara rẹ̀ lára àwọn ohun tí í ṣe ti baba wa.”

2. Jákọ́bù sì ṣàkíyèsí pé ìwà Lábánì sí òun ti yí padà sí ti àtẹ̀yìnwá.

3. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jákọ́bù pé, “Padà lọ sí ilẹ̀ àwọn baba à rẹ, sí ọ̀dọ̀ àwọn ará rẹ, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ.”

Jẹ́nẹ́sísì 31