Jẹ́nẹ́sísì 27:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà náà ni Rèbékà mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rèbékà, ó sì fi wọ Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ kékeré.

16. Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ó yọ silẹ̀ lọ́rùn rẹ̀ tí kò ní irun.

17. Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

18. Jákọ́bù wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi”,Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?”

19. Jákọ́bù sì fèsì pé, “Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí rẹ, mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí, jọ̀wọ̀ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran-igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.”

20. Ísáákì tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?”Jákọ́bù sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.”

21. Nígbà náà ni Ísáákì wí fún Jákọ́bù pé, “Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Ísọ̀ ọmọ mi ni ní tòótọ́ tàbí òun kọ́”

22. Jákọ́bù sì súnmọ Ísáákì baba rẹ̀. Ísáákì sì fọwọ́ kàn-án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jákọ́bù; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Ísọ̀.”

23. Kò sì dá Jákọ́bù mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ nírun bí i ti Ísọ̀ arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún-un

Jẹ́nẹ́sísì 27