Jẹ́nẹ́sísì 27:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Jákọ́bù sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rèbékà sì se oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Ísáákì fẹ́ràn.

15. Nígbà náà ni Rèbékà mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rèbékà, ó sì fi wọ Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ kékeré.

16. Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ó yọ silẹ̀ lọ́rùn rẹ̀ tí kò ní irun.

17. Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

18. Jákọ́bù wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi”,Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?”

19. Jákọ́bù sì fèsì pé, “Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí rẹ, mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí, jọ̀wọ̀ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran-igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.”

20. Ísáákì tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?”Jákọ́bù sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.”

21. Nígbà náà ni Ísáákì wí fún Jákọ́bù pé, “Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Ísọ̀ ọmọ mi ni ní tòótọ́ tàbí òun kọ́”

22. Jákọ́bù sì súnmọ Ísáákì baba rẹ̀. Ísáákì sì fọwọ́ kàn-án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jákọ́bù; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Ísọ̀.”

Jẹ́nẹ́sísì 27