Jẹ́nẹ́sísì 27:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Jákọ́bù sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rèbékà sì se oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Ísáákì fẹ́ràn.

15. Nígbà náà ni Rèbékà mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rèbékà, ó sì fi wọ Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ kékeré.

16. Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ó yọ silẹ̀ lọ́rùn rẹ̀ tí kò ní irun.

17. Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

18. Jákọ́bù wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi”,Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?”

Jẹ́nẹ́sísì 27