Jẹ́nẹ́sísì 24:54-59 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

54. Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà.Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.”

55. Ṣùgbọ́n arákùnrin Rèbékà àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, “A fẹ́ kí Rèbékà wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn ìyẹn, ìwọ le máa mu lọ.”

56. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá mi dúró, Olúwa ṣáà ti ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ẹ rán mi lọ, kí èmi kí ó le è tọ olúwa à mi lọ.”

57. Nígbà náà ni wọ́n sọ pé, “Jẹ́ kí a pe ọmọ náà gan-an kí a sì bi í”

58. Wọ́n sì pe Rèbékà wọ́n sì bi í, wí pé, “Ṣe ìwọ yóò bá ọkùnrin yìí lọ.”Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò lọ”

59. Wọ́n sì gbà kí Rèbékà àti olùtọ́jú rẹ̀, pẹ̀lú ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ má a lọ.

Jẹ́nẹ́sísì 24