27. Wí pe, “Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ábúráhámù olúwa mi ti kò jẹ́ kí àánú àti òtítọ́ rẹ̀ kí ó yẹ̀ lọ́dọ̀ olúwa mi. Ní ti èmi Olúwa ti darí ìrìn-àjò mi sí ilé ìbátan olúwa mi.”
28. Ọmọbìnrin náà sì sáré, ó sì lọ sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀.
29. Rèbékà ní arákùnrin tí ń jẹ́ Lábánì; Lábánì sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò.
30. Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rèbékà sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ràkunmí wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun-omi.
31. Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa, Èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ràkunmí rẹ.”
32. Ọkùnrin náà sì bá Lábánì lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ràkunmí rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn.
33. Wọ́n sì gbé oúnjẹ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo níí sọ.”Lábánì sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.”
34. Nítorí náà ó wí pé, “Ìránṣẹ́ Ábúráhámù ni èmi.
35. Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún-un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin àti ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.