Jẹ́nẹ́sísì 17:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ábúráhámù sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún? Ṣárà tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún yóò ha bímọ bí”.

18. Ábúráhámù sì wí fún Ọlọ́run pé, “Ṣá à jẹ́ kí Ísímáélì kí ó wà láàyè lábẹ́ ìbùkún rẹ.”

19. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Ṣárà aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísáákì, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 17