Jẹ́nẹ́sísì 17:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ìgbà tí Ábúrámù di ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára, máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù.

2. Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.”

3. Ábúrámù sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé.

4. “Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí. Ìwọ yóò di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀.

5. A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Ábúrámù mọ́, bí kò ṣe Ábúráhámù, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀ èdè púpọ̀.

6. Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde.

7. Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrin èmi àti ìwọ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrin irú ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ.

Jẹ́nẹ́sísì 17