Jẹ́nẹ́sísì 13:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ábúrámù sì gòkè láti Éjíbítì lọ sí Nẹ́gẹ́fù ní ìhà gúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọ́tì pẹ̀lú.

2. Ábúrámù sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ní ẹran-ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

3. Láti Gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Bẹ́tẹ́lì, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú ri lágbedeméjì Bẹ́tẹ́lì àti Áì.

4. Ní ibi tí ó ti tẹ́ pẹpẹ sí rí tẹ́lẹ̀; Ábúrámù sì ké pe orúkọ Olúwa.

5. Lọ́tì, tí ó ń bá Ábúrámù kiri pẹ̀lú ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àwọn àgọ́ tirẹ̀.

6. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun-ìní wọn pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, débi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.

7. Èdè àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn darandaran Ábúrámù àti ti Lọ́tì. Àwọn ará a Kénánì àti àwọn ará Pérísítì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.

8. Ábúrámù sì wí fún Lọ́tì pé, “Mo fẹ́ kí a fòpin sí èdè àìyedè tí ó wà láàrin èmi àti ìwọ àti láàrin àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí ni wá.

Jẹ́nẹ́sísì 13