12. nígbà tí àwọn ara Éjíbítì bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí.
13. Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”
14. Nígbà tí Ábúrámù dé Éjíbítì, àwọn ará Éjíbítì ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi.
15. Nígbà tí àwọn ìjòyè Fáráò sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú u Fáráò, Wọ́n sì mú un lọ sí ààfin,
16. Ó sì kẹ́ Ábúrámù dáradára nítorí Ṣáráì, Ábúrámù sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú u ràkunmí.
17. Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-àrùn búburú sí Fáráò àti ilé rẹ̀, nítorí Sáráì aya Ábúrámù.
18. Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Ábúrámù, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí n ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe?