Jẹ́nẹ́sísì 10:30-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Méṣà títí dé Ṣéfárì, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà oòrùn.

31. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣémù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀ èdè wọn.

32. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Nóà gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀ èdè wọn. Ní ipaṣẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.

Jẹ́nẹ́sísì 10