21. A bí àwọn ọmọ fún Ṣémù tí Jáfétì jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣémù sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Ébérì.
22. Àwọn ọmọ Ṣémù ni:Élámù, Ásọ̀, Áfákísádì, Lúdì àti Árámù.
23. Àwọn ọmọ Árámù ni:Úsì, Úlì, Gétérì àti Méṣékì.
24. Áfákísádì ni baba Ṣélà,Ṣélà yìí sì ni ó bí Ébérì.
25. Ébérì sì bí ọmọ méjì:ọ̀kan sì ń jẹ́ Pélégì, nítorí ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ ayé pín sí oríṣìíríṣìí ẹ̀yà àti èdè. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítanì.
26. Jókítanì sì bíÁlímádádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì àti Jérà.