19. Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kénánì sì dé Ṣídónì, lọ sí Gérárì títí dé Gásà, lọ sí Sódómù, Gòmórà, Ádímà àti Ṣébóìmù, títí dé Láṣà.
20. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ámù, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
21. A bí àwọn ọmọ fún Ṣémù tí Jáfétì jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣémù sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Ébérì.
22. Àwọn ọmọ Ṣémù ni:Élámù, Ásọ̀, Áfákísádì, Lúdì àti Árámù.
23. Àwọn ọmọ Árámù ni:Úsì, Úlì, Gétérì àti Méṣékì.
24. Áfákísádì ni baba Ṣélà,Ṣélà yìí sì ni ó bí Ébérì.
25. Ébérì sì bí ọmọ méjì:ọ̀kan sì ń jẹ́ Pélégì, nítorí ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ ayé pín sí oríṣìíríṣìí ẹ̀yà àti èdè. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítanì.
26. Jókítanì sì bíÁlímádádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì àti Jérà.
27. Hádórámù, Húsálì, Díbílà.
28. Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà.