Jákọ́bù 5:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń se ní agbára púpọ̀.

17. Ènìyàn onírúurú ìwà bí àwa ni Èlíjà, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà.

18. Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.

19. Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá sìnà kúrò nińu òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà;

Jákọ́bù 5