Jákọ́bù 2:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí talákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí;

3. Tí ẹ̀yin sì bu ọla fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún talákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi;”

4. Ẹ̀yin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí?

5. Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn talákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ?

6. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu talákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n ẹ̀yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́?

7. Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?

8. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára.

9. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsáájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin.

10. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀.

11. Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Má ṣe ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Má ṣe pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.

Jákọ́bù 2