Ísíkẹ́lì 46:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan pẹ̀lú àgbò kan, àti pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá se wu onílúlùkù, Pẹ̀lú hini òróró kan fún éfà kan.

12. Nígbà tí ọmọ aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí ó wà ni sísí sílẹ̀ fún-un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, oun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu ọ̀nà.

13. “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀.

14. Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú éfà àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.

15. Nítorí náà ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

Ísíkẹ́lì 46