1. “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí Ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmí àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a sí i.
2. Ọmọ aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kangun sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ilẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́.