12. Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèkéé kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèkéé sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.
13. Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèkéé kan títí dé òkè àdojúkọ ọ̀kan; jínjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó sí sílẹ̀ sí àdojúkọ ọ̀kan.
14. Ó wọ̀n ọ́n lọ sí àwọn ojú àwọn ìgbéró ògiri gbogbo rẹ̀ yí inú òjú ọ̀nà ó jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Ìwọ̀n náà tó àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ àgbàlá.
15. Ìjìnà ẹnu ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèkéé náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.