Ísíkẹ́lì 37:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Ísírẹ́lì, Ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀ èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.

23. Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

24. “ ‘Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ Ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́.

25. Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, Ìránṣẹ́ mi Dáfídì ni yóò jẹ́ ọmọ Aládé wọn láéláé.

26. Èmi yóò dá májẹ̀mu àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mu títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì ṣọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárin wọn títí láé.

27. Ibùgbé mí yóò wà pẹ̀lú wọn, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.

Ísíkẹ́lì 37