18. “Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’
19. Ṣọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò gba igi Jósẹ́fù—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Éfúráímù—àti ti ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Júdà, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’
20. Gbé igi pátakó tí ó kọ nǹkan síi sókè ní iwájú wọn,
21. kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn.
22. Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Ísírẹ́lì, Ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀ èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.
23. Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
24. “ ‘Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ Ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́.