Ísíkẹ́lì 36:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀ èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.

8. “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Ísírẹ́lì, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí.

9. Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́,

10. èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a óò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́.

Ísíkẹ́lì 36