Ísíkẹ́lì 31:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹ́ta ọdún kọkànlá, ọrọ Olúwa tọ̀ mí wá:

2. “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Fáráò Ọba Éjíbítì àti sí ìjọ rẹ̀:“ ‘Ta ní a le fi wé ọ ní ọlá ńlá?

3. Kíyèsí Ásíríà, tí ó jẹ́ òpépé igi niLébánónì ní ìgbà kan rí,pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣe ìji bo igbó náà;tí ó ga sókè,òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.

4. Omi mú un dàgbà sókè:orísun omi tí ó jìnlẹ̀ mú kí o dàgbà sókè;àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.

5. Nítorí náà ó ga sí òkè fíofíoju gbogbo igi orí pápá lọ;Ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i:àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

Ísíkẹ́lì 31