19. “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.
20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.
21. “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.
22. “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.
23. “ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.
24. Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.
25. “ ‘Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èròní ọjà rẹa ti mú ọ gbilẹ̀a sì ti ṣe ọ́ lógoní àárin gbungbun òkun
26. Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọwá sínú omi ńlá.Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ní àárin gbùngbùn òkun.
27. Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,àwọn atọ́kọ̀ rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.Àwọn oníbárà rẹ àti gbogbo àwọnjagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹàti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹtí ó wà ní àárin rẹyóò rì sínú àárin gbùngbùn òkunní ọjọ́ ìparun rẹ.
28. Ilẹ̀ etí òkun yóò mìnítorí ìró igbe àwọn atọ́kọ̀ rẹ.
29. Gbogbo àwọn alájẹ̀àwọn atukọ̀àti àwọn atọ́kọ̀ ojú òkun;yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.
30. Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọwọn yóò sì sunkún kíkorò lé ọ lóríwọn yóò ku eruku lé orí ara wọnwọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.